O. Sol 7:5-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Ori rẹ dabi Karmeli lara rẹ, ati irun ori rẹ bi purpili; a fi aidì irun rẹ di ọba mu.

6. O ti li ẹwà to, o si ti dara to, iwọ olufẹ mi ninu adùn ifẹ!

7. Iduro rẹ yi dabi igi ọ̀pẹ ati ọmú rẹ bi ṣiri eso àjara.

8. Mo ni, emi o gùn ọ̀pẹ lọ, emi o di ẹka rẹ̀ mu: pẹlupẹlu nisisiyi ọmú rẹ pẹlu yio dabi ṣiri àjara, ati õrùn imú rẹ bi eso appili;

9. Ati ẹnu rẹ bi ọti-waini ti o dara jù, ti o sọkalẹ kẹlẹkẹlẹ fun olufẹ mi, ti o nmu ki etè awọn ti o sùn ki o sọ̀rọ.

10. Ti olufẹ mi li emi iṣe, ifẹ rẹ̀ si mbẹ si mi.

11. Wá, olufẹ mi, jẹ ki a lọ si pápa; jẹ ki a wọ̀ si iletò wọnni.

O. Sol 7