3. Ọmú rẹ mejeji dabi abo ọmọ agbọnrin meji ti iṣe ìbejì.
4. Ọrùn rẹ dabi ile iṣọ ehin-erin; oju rẹ dabi adagun ni Heṣboni, lẹba ẹnu-bode Batrabbimu: imú rẹ dabi ile-iṣọ Lebanoni ti o kọju si ihà Damasku.
5. Ori rẹ dabi Karmeli lara rẹ, ati irun ori rẹ bi purpili; a fi aidì irun rẹ di ọba mu.
6. O ti li ẹwà to, o si ti dara to, iwọ olufẹ mi ninu adùn ifẹ!
7. Iduro rẹ yi dabi igi ọ̀pẹ ati ọmú rẹ bi ṣiri eso àjara.
8. Mo ni, emi o gùn ọ̀pẹ lọ, emi o di ẹka rẹ̀ mu: pẹlupẹlu nisisiyi ọmú rẹ pẹlu yio dabi ṣiri àjara, ati õrùn imú rẹ bi eso appili;