1. LI oru lori akete mi, mo wá ẹniti ọkàn mi fẹ: emi wá a, ṣugbọn emi kò ri i.
2. Emi o dide nisisiyi, emi o si rìn lọ ni ilu, ni igboro, ati li ọ̀na gbòro ni emi o wá ẹniti ọkàn mi fẹ: emi wá a, ṣugbọn emi kò ri i.
3. Awọn oluṣọ ti nrìn ilu yika ri mi: mo bère pe, Ẹ ha ri ẹniti ọkàn mi fẹ bi?