O. Sol 1:12-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Nigbati ọba wà ni ibujoko ijẹun rẹ̀, ororo mi rán õrun rẹ̀ jade.

13. Idi ojia ni olufẹ ọ̀wọ́n mi si mi; on o ma gbe ãrin ọmu mi.

14. Olufẹ mi ri si mi bi ìdi ìtànná igi kipressi ni ọgba-ajara Engedi.

15. Wò o, iwọ li ẹwà, olufẹ mi; wò o, iwọ li ẹwà: iwọ li oju àdaba.

16. Wò o, iwọ li ẹwà, olufẹ mi, nitõtọ, o wuni: ibusun wa pẹlu ni itura.

17. Igi kedari ni iti-igi ile wa, igi firi si ni ẹkẹ́ wa.

O. Sol 1