O. Daf 98:2-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Oluwa ti sọ igbala rẹ̀ di mimọ̀: ododo rẹ̀ li o ti fi hàn nigbangba li ojú awọn keferi.

3. O ti ranti ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ si awọn ara ile Israeli: gbogbo opin aiye ti ri igbala Ọlọrun wa.

4. Ẹ ho iho ayọ̀ si Oluwa, gbogbo aiye: ẹ ho yè, ẹ yọ̀, ki ẹ si ma kọrin iyìn.

O. Daf 98