1. ẸWÁ, ẹ jẹ ki a kọrin si Oluwa: ẹ jẹ ki a hó iho ayọ̀ si apata igbala wa.
2. Ẹ jẹ ki a fi ọpẹ wá si iwaju rẹ̀, ki a si fi orin mimọ́ hó iho ayọ̀ si ọdọ rẹ̀.
3. Nitori Oluwa, Ọlọrun ti o tobi ni, ati Ọba ti o tobi jù gbogbo oriṣa lọ,
4. Ni ikawọ ẹniti ibi ọgbun ilẹ wà: giga awọn òke nla ni tirẹ̀ pẹlu.
5. Tirẹ̀ li okun, on li o si dá a: ọwọ rẹ̀ li o si dá iyangbẹ ilẹ.
6. Ẹ wá, ẹ jẹ ki a wolẹ, ki a tẹriba: ẹ jẹ ki a kunlẹ niwaju Oluwa, Ẹlẹda wa.
7. Nitori on li Ọlọrun wa; awa si li enia papa rẹ̀, ati agutan ọwọ rẹ̀. Loni bi ẹnyin o ba gbọ́ ohùn rẹ̀,
8. Ẹ má sé aiya nyin le, bi ti Meriba ati bi ọjọ na ni Massa, li aginju.
9. Nigbati awọn baba nyin dan mi wò, ti nwọn wadi mi, ti nwọn si ri iṣẹ mi.