O. Daf 94:10-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ẹniti nnà awọn orilẹ-ède, o ha le ṣe alaiṣe olutọ́? on li ẹniti nkọ́ enia ni ìmọ.

11. Oluwa mọ̀ ìro-inu enia pe: asan ni nwọn.

12. Ibukún ni fun enia na ẹniti iwọ nà, Oluwa, ti iwọ si kọ́ lati inu ofin rẹ wá;

13. Ki iwọ ki o le fun u ni isimi kuro li ọjọ ibi, titi a o fi wà iho silẹ fun enia buburu.

O. Daf 94