O. Daf 91:7-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ẹgbẹrun yio ṣubu li ẹgbẹ rẹ, ati ẹgbarun li apa ọtún rẹ: ṣugbọn kì yio sunmọ ọdọ rẹ.

8. Kiki oju rẹ ni iwọ o ma fi ri, ti o si ma fi wo ère awọn enia buburu.

9. Nitori iwọ, Oluwa, ni iṣe ãbo mi, iwọ ti fi Ọga-ogo ṣe ibugbe rẹ.

10. Buburu kan kì yio ṣubu lu ọ, bẹ̃li arunkarun kì yio sunmọ ile rẹ.

O. Daf 91