2. Jẹ ki adura mi ki o wá si iwaju rẹ: dẹ eti rẹ silẹ si igbe mi.
3. Nitori ti ọkàn mi kún fun ipọnju, ẹmi mi si sunmọ isa-okú.
4. A kà mi pẹlu kún awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò: emi dabi ọkunrin ti kò ni ipá.
5. Ẹniti a kọ̀ silẹ lãrin awọn okú, bi awọn ẹni pipa ti o dubulẹ ni isa-okú, ẹniti iwọ kò ranti mọ́: a si ke wọn kuro nipa ọwọ rẹ.
6. Iwọ ti fi mi le ibi isalẹ ti o jìn julọ, ninu okunkun, ninu ọgbun.
7. Ibinu rẹ lẹ̀ mọ mi lara kikan, iwọ si ti fi riru omi rẹ gbogbo ba mi ja.