9. Gbogbo awọn orilẹ-ède ti iwọ da ni yio wá, nwọn o si sìn niwaju rẹ, Oluwa; nwọn o si ma fi ogo fun orukọ rẹ.
10. Nitoripe iwọ pọ̀, iwọ si nṣe ohun iyanu: iwọ nikan li Ọlọrun.
11. Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o ma rìn ninu otitọ rẹ: mu aiya mi ṣọkan lati bẹ̀ru orukọ rẹ.
12. Emi o yìn ọ, Oluwa Ọlọrun mi, tinutinu mi gbogbo: emi o si ma fi ogo fun orukọ rẹ titi lai.
13. Nitoripe nla li ãnu rẹ si mi: iwọ si ti gbà ọkàn mi lọwọ isa-okú jijin.
14. Ọlọrun, awọn agberaga dide si mi, ati ijọ awọn alagbara nwá ọkàn mi kiri; nwọn kò si fi ọ pè li oju wọn.