1. KỌRIN soke si Ọlọrun, ipa wa: ẹ ho iho ayọ̀ si Ọlọrun Jakobu.
2. Ẹ mu orin mimọ́, ki ẹ si mu ìlu wa, duru didùn pẹlu ohun-elo orin mimọ́.
3. Ẹ fun ipè li oṣù titún, ni ìgbà ti a lana silẹ, li ọjọ ajọ wa ti o ni ironu.
4. Nitori eyi li aṣẹ fun Israeli, ati ofin Ọlọrun Jakobu.