O. Daf 78:9-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Awọn ọmọ Efraimu ti o hamọra ogun, ti nwọn mu ọrun, nwọn yipada li ọjọ ogun.

10. Nwọn kò pa majẹmu Ọlọrun mọ́, nwọn si kọ̀ lati ma rìn ninu ofin rẹ̀.

11. Nwọn si gbagbe iṣẹ rẹ̀, ati ohun iyanu rẹ̀, ti o ti fi hàn fun wọn.

12. Ohun iyanu ti o ṣe niwaju awọn baba wọn ni ilẹ Egipti, ani ni igbẹ Soani.

13. O pin okun ni ìya, o si mu wọn là a ja; o si mu omi duro bi bèbe.

14. Li ọsan pẹlu o fi awọsanma ṣe amọna wọn, ati li oru gbogbo pẹlu imọlẹ iná.

15. O sán apata li aginju, o si fun wọn li omi mímu lọpọlọpọ bi ẹnipe lati inu ibú wá.

16. O si mu iṣàn-omi jade wá lati inu apata, o si mu omi ṣàn silẹ bi odò nla.

17. Nwọn si tún ṣẹ̀ si i; ni ṣiṣọtẹ si Ọga-ogo li aginju.

18. Nwọn si dán Ọlọrun wò li ọkàn wọn, ni bibère onjẹ fun ifẹkufẹ wọn.

19. Nwọn si sọ̀rọ si Ọlọrun; nwọn wipe, Ọlọrun ha le tẹ́ tabili li aginju?

20. Wò o! o lù apata, omi si tú jade, iṣàn-omi si kún pupọ; o ha le funni li àkara pẹlu? o ha le pèse ẹran fun awọn enia rẹ̀?

21. Nitorina, Oluwa gbọ́ eyi, o binu: bẹ̃ni iná ràn ni Jakobu, ibinu si ru ni Israeli;

22. Nitori ti nwọn kò gbà Ọlọrun gbọ́, nwọn kò si gbẹkẹle igbala rẹ̀.

23. O paṣẹ fun awọsanma lati òke wá, o si ṣi ilẹkùn ọrun silẹ.

O. Daf 78