51. O si kọlu gbogbo awọn akọbi ni Egipti, olori agbara wọn ninu agọ Hamu:
52. Ṣugbọn o mu awọn enia tirẹ̀ lọ bi agutan, o si ṣe itọju wọn ni iju bi agbo-ẹran.
53. O si ṣe amọna wọn li alafia, bẹ̃ni nwọn kò si bẹ̀ru: ṣugbọn okun bò awọn ọta wọn mọlẹ.
54. O si mu wọn wá si eti ibi-mimọ́ rẹ̀, ani si òke yi ti ọwọ ọtún rẹ̀ ti rà.
55. O tì awọn keferi jade pẹlu kuro niwaju wọn, o si fi tita okùn pinlẹ fun wọn ni ilẹ-ini, o si mu awọn ẹya Israeli joko ninu agọ wọn.
56. Ṣugbọn nwọn dan a wò, nwọn si ṣọ̀tẹ si Ọlọrun Ọga-ogo, nwọn kò si pa ẹri rẹ̀ mọ́.