47. O fi yinyin pa àjara wọn, o si fi yinyin nla pa igi sikamore wọn.
48. O fi ohun ọ̀sin wọn pẹlu fun yinyin, ati agbo-ẹran wọn fun manamana.
49. O mu kikoro ibinu rẹ̀ wá si wọn lara, irunu ati ikannu, ati ipọnju, nipa riran angeli ibi sinu wọn.
50. O ṣina silẹ fun ibinu rẹ̀; kò da ọkàn wọn si lọwọ ikú, ṣugbọn o fi ẹmi wọn fun àjakalẹ-àrun.
51. O si kọlu gbogbo awọn akọbi ni Egipti, olori agbara wọn ninu agọ Hamu:
52. Ṣugbọn o mu awọn enia tirẹ̀ lọ bi agutan, o si ṣe itọju wọn ni iju bi agbo-ẹran.