O. Daf 78:40-47 Yorùbá Bibeli (YCE)

40. Igba melo-melo ni nwọn sọ̀tẹ si i li aginju, ti nwọn si bà a ninu jẹ ninu aṣálẹ!

41. Nitõtọ, nwọn yipada, nwọn si dan Ọlọrun wò, nwọn si ṣe aropin Ẹni-Mimọ́ Israeli.

42. Nwọn kò ranti ọwọ rẹ̀, tabi ọjọ nì ti o gbà wọn lọwọ ọta.

43. Bi o ti ṣe iṣẹ-àmi rẹ̀ ni Egipti, ati iṣẹ iyanu rẹ̀ ni igbẹ Soani.

44. Ti o si sọ odò wọn di ẹ̀jẹ; ati omi ṣiṣan wọn, ti nwọn kò fi le mu u.

45. O rán eṣinṣin sinu wọn, ti o jẹ wọn; ati ọpọlọ, ti o run wọn.

46. O fi eso ilẹ wọn fun kokoro pẹlu, ati iṣẹ wọn fun ẽṣú.

47. O fi yinyin pa àjara wọn, o si fi yinyin nla pa igi sikamore wọn.

O. Daf 78