1. FI eti silẹ, ẹnyin enia mi, si ofin mi: dẹ eti nyin silẹ si ọ̀rọ ẹnu mi.
2. Emi o ya ẹnu mi li owe: emi o sọ ọ̀rọ atijọ ti o ṣokunkun jade.
3. Ti awa ti gbọ́, ti a si ti mọ̀, ti awọn baba wa si ti sọ fun wa.
4. Awa kì yio pa wọn mọ́ kuro lọdọ awọn ọmọ wọn, ni fifi iyìn Oluwa, ati ipa rẹ̀, ati iṣẹ iyanu ti o ti ṣe hàn fun iran ti mbọ.
5. Nitori ti o gbé ẹri kalẹ ni Jakobu, o si sọ ofin kan ni Israeli, ti o ti pa li aṣẹ fun awọn baba wa pe, ki nwọn ki o le sọ wọn di mimọ̀ fun awọn ọmọ wọn.
6. Ki awọn iran ti mbọ̀ ki o le mọ̀, ani awọn ọmọ ti a o bi: ti yio si dide, ti yio si sọ fun awọn ọmọ wọn:
7. Ki nwọn ki o le ma gbé ireti wọn le Ọlọrun, ki nwọn ki o má si ṣe gbagbe iṣẹ Ọlọrun, ṣugbọn ki nwọn ki o pa ofin rẹ̀ mọ́.