O. Daf 77:5-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Emi ti nrò ọjọ atijọ, ọdun igbani.

6. Mo ranti orin mi li oru: emi mba aiya mi sọ̀rọ: ọkàn mi si nṣe awari jọjọ.

7. Oluwa yio ha ṣa ni tì lailai? kì o si ṣe oju rere mọ́?

8. Anu rẹ̀ ha lọ lailai? ileri rẹ̀ ha yẹ̀ titi lai?

9. Ọlọrun ha gbagbe lati ṣe oju rere? ninu ibinu rẹ̀ o ha sé irọnu ãnu rẹ̀ mọ́?

10. Emi wipe, Eyi li ailera mi! eyi li ọdun ọwọ ọtún Ọga-ogo!

11. Emi o ranti iṣẹ Oluwa: nitõtọ emi o ranti iṣẹ iyanu rẹ atijọ.

12. Ṣugbọn emi o ma ṣe àṣaro gbogbo iṣẹ rẹ pẹlu, emi o si ma sọ̀rọ iṣẹ rẹ.

O. Daf 77