O. Daf 77:17-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Awọsanma dà omi silẹ: ojusanma rán iró jade: ọfà rẹ jade lọ pẹlu.

18. Ohùn ãrá rẹ nsan li ọrun: manamana nkọ si aiye, ilẹ nwa-rìri, o si mì.

19. Ọ̀na rẹ mbẹ li okun, ati ipa rẹ ninu awọn omi nla, ipasẹ rẹ li a kò si mọ̀.

20. Iwọ dà awọn enia rẹ bi ọ̀wọ-ẹran nipa ọwọ Mose ati Aaroni.

O. Daf 77