O. Daf 77:13-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ọlọrun, ọ̀na rẹ mbẹ ninu ìwa-mimọ́: tali alagbara ti o tobi bi Ọlọrun?

14. Iwọ li Alagbara ti nṣe iṣẹ iyanu: iwọ li o ti fi ipá rẹ hàn ninu awọn enia.

15. Iwọ li o ti fi apá rẹ rà awọn enia rẹ pada, awọn ọmọ Jakobu ati Josefu.

16. Omi ri ọ, Ọlọrun, omi ri ọ, ẹ̀ru bà wọn: nitõtọ ara ibú kò balẹ.

17. Awọsanma dà omi silẹ: ojusanma rán iró jade: ọfà rẹ jade lọ pẹlu.

18. Ohùn ãrá rẹ nsan li ọrun: manamana nkọ si aiye, ilẹ nwa-rìri, o si mì.

19. Ọ̀na rẹ mbẹ li okun, ati ipa rẹ ninu awọn omi nla, ipasẹ rẹ li a kò si mọ̀.

20. Iwọ dà awọn enia rẹ bi ọ̀wọ-ẹran nipa ọwọ Mose ati Aaroni.

O. Daf 77