O. Daf 73:2-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, ẹsẹ mi fẹrẹ yẹ̀ tan; ìrin mi fẹrẹ yọ́ tan.

3. Nitori ti emi ṣe ilara si awọn aṣe-fefe, nigbati mo ri alafia awọn enia buburu.

4. Nitoriti kò si irora ninu ikú wọn: agbara wọn si pọ̀.

5. Nwọn kò ni ipin ninu iyọnu enia; bẹ̃ni a kò si wahala wọn pẹlu ẹlomiran.

O. Daf 73