O. Daf 73:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NITÕTỌ Ọlọrun ṣeun fun Israeli, fun iru awọn ti iṣe alaiya mimọ́.

2. Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, ẹsẹ mi fẹrẹ yẹ̀ tan; ìrin mi fẹrẹ yọ́ tan.

3. Nitori ti emi ṣe ilara si awọn aṣe-fefe, nigbati mo ri alafia awọn enia buburu.

4. Nitoriti kò si irora ninu ikú wọn: agbara wọn si pọ̀.

5. Nwọn kò ni ipin ninu iyọnu enia; bẹ̃ni a kò si wahala wọn pẹlu ẹlomiran.

6. Nitorina ni igberaga ṣe ká wọn lọrun bi ẹ̀wọn ọṣọ́; ìwa-ipa bò wọn mọlẹ bi aṣọ.

7. Oju wọn yọ jade fun isanra: nwọn ní jù bi ọkàn wọn ti nfẹ lọ.

8. Nwọn nṣẹsin, nwọn si nsọ̀rọ buburu niti inilara: nwọn nsọ̀rọ lati ibi giga.

9. Nwọn gbé ẹnu wọn le ọrun, ahọn wọn si nrìn ilẹ já.

10. Nitorina li awọn enia rẹ̀ ṣe yipada si ihin: ọ̀pọlọpọ omi li a si npọn jade fun wọn.

11. Nwọn si wipe, Ọlọrun ti ṣe mọ̀? ìmọ ha wà ninu Ọga-ogo?

12. Kiyesi i, awọn wọnyi li alaìwa-bi-ọlọrun, ẹniti aiye nsan, nwọn npọ̀ li ọrọ̀.

13. Nitõtọ li asan ni mo wẹ̀ aiya mi mọ́, ti mo si wẹ̀ ọwọ mi li ailẹ̀ṣẹ.

O. Daf 73