O. Daf 71:12-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Ọlọrun, máṣe jina si mi: Ọlọrun mi, yara si iranlọwọ mi.

13. Jẹ ki nwọn ki o dãmu, ki a si run awọn ti nṣe ọta ọkàn mi, ki a si fi ẹ̀gan ati àbuku bo awọn ti nwá ifarapa mi.

14. Ṣugbọn emi o ma reti nigbagbogbo, emi o si ma fi iyìn kún iyìn rẹ.

15. Ẹnu mi yio ma fi ododo rẹ ati igbala rẹ hàn li ọjọ gbogbo; emi kò sa mọ̀ iye rẹ̀.

16. Emi o wá li agbara Oluwa Ọlọrun; emi o ma da ọ̀rọ ododo rẹ sọ, ani tirẹ nikan.

17. Ọlọrun, iwọ ti kọ́ mi lati igba ewe mi wá: ati di isisiyi li emi ti nsọ̀rọ iṣẹ iyanu rẹ.

18. Pẹlupẹlu, nigbati emi di arugbo tan ti mo hewu, Ọlọrun máṣe kọ̀ mi; titi emi o fi fi ipá rẹ hàn fun iran yi, ati agbara rẹ fun gbogbo awọn ara ẹ̀hin.

19. Ọlọrun ododo rẹ ga jọjọ pẹlu, ẹniti o ti nṣe nkan nla: Ọlọrun, tali o dabi iwọ!

O. Daf 71