O. Daf 71:12-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Ọlọrun, máṣe jina si mi: Ọlọrun mi, yara si iranlọwọ mi.

13. Jẹ ki nwọn ki o dãmu, ki a si run awọn ti nṣe ọta ọkàn mi, ki a si fi ẹ̀gan ati àbuku bo awọn ti nwá ifarapa mi.

14. Ṣugbọn emi o ma reti nigbagbogbo, emi o si ma fi iyìn kún iyìn rẹ.

O. Daf 71