9. Nitori ti itara ile rẹ ti jẹ mi tan; ati ẹ̀gan awọn ti o gàn ọ, ṣubu lù mi.
10. Nigbati mo sọkun, ti mo si nfi àwẹ jẹ ara mi ni ìya, eyi na si di ẹ̀gan mi.
11. Emi fi aṣọ ọ̀fọ sẹ aṣọ mi pẹlu: mo si di ẹni-owe fun wọn.
12. Awọn ti o joko li ẹnu-bode nsọ̀rọ si mi; emi si di orin awọn ọmuti.
13. Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, iwọ li emi ngbadura mi si, Oluwa, ni igba itẹwọgba: Ọlọrun, ninu ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ da mi lohùn, ninu otitọ igbala rẹ.
14. Yọ mi kuro ninu ẹrẹ̀, má si ṣe jẹ ki emi ki o rì: gbigbà ni ki a gbà mi lọwọ awọn ti o korira mi, ati ninu omi jijìn wọnni.
15. Máṣe jẹ ki kikún-omi ki o bò mi mọlẹ, bẹ̃ni ki o máṣe jẹ ki ọgbun ki o gbé mi mì, ki o má si ṣe jẹ ki iho ki o pa ẹnu rẹ̀ de mọ́ mi.
16. Oluwa, da mi lohùn; nitori ti iṣeun ifẹ rẹ dara, yipada si mi gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ irọnu ãnu rẹ.
17. Ki o má si ṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lara iranṣẹ rẹ: emi sa wà ninu ipọnju; yara, da mi lohùn.
18. Sunmọ ọkàn mi, si rà a pada: gbà mi nitori awọn ọta mi.
19. Iwọ ti mọ̀ ẹ̀gan mi ati ìtiju mi, ati alailọla mi: gbogbo awọn ọta mi li o wà niwaju rẹ.