O. Daf 68:23-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Ki ẹsẹ rẹ ki o le pọ́n ninu ẹ̀jẹ awọn ọta rẹ, ati àhọn awọn aja rẹ ninu rẹ̀ na.

24. Nwọn ti ri ìrin rẹ, Ọlọrun; ani ìrin Ọlọrun mi, Ọba mi, ninu ibi mimọ́ nì.

25. Awọn akọrin lọ niwaju, awọn olohun-elo orin kẹhin; larin awọn ọmọbinrin ti nwọn nlu ìlu.

O. Daf 68