11. Oluwa ti sọ̀rọ: ọ̀pọlọpọ si li ogun awọn ẹniti nfi ayọ̀ rohin rẹ̀:
12. Awọn ọba awọn ẹgbẹ ogun sa, nwọn sa lọ: obinrin ti o si joko ni ile ni npin ikogun na.
13. Nigbati ẹnyin dubulẹ larin agbo ẹran, nigbana ni ẹnyin o dabi iyẹ adaba ti a bò ni fadaka, ati ìyẹ́ rẹ̀ pẹlu wura pupa.
14. Nigbati Olodumare tú awọn ọba ká ninu rẹ̀, o dabi òjo-didì ni Salmoni.
15. Òke Ọlọrun li òke Baṣani: òke ti o ni ori pupọ li òke Baṣani.