O. Daf 68:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. KI Ọlọrun ki o dide, ki a si tú awọn ọta rẹ̀ ka: ki awọn ti o korira rẹ̀ pẹlu, ki nwọn ki o salọ kuro niwaju rẹ̀.

2. Bi ẽfin ti ifẹ lọ, bẹ̃ni ki o fẹ́ wọn lọ; bi ida ti iyọ́ niwaju iná, bẹ̃ni ki enia buburu ki o ṣegbe niwaju Ọlọrun.

3. Ṣugbọn jẹ ki inu awọn olododo ki o dùn; ki nwọn ki o yọ̀ niwaju Ọlọrun. nitõtọ, ki nwọn ki o yọ̀ gidigidi.

4. Ẹ kọrin si Ọlọrun, ẹ kọrin iyin si orukọ rẹ̀: ẹ la ọ̀na fun ẹniti nrekọja li aginju nipa JAH, orukọ rẹ̀, ki ẹ si ma yọ̀ niwaju rẹ̀.

5. Baba awọn alainibaba ati onidajọ awọn opó, li Ọlọrun ni ibujoko rẹ̀ mimọ́.

O. Daf 68