O. Daf 63:7-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nitoripe iwọ li o ti nṣe iranlọwọ mi, nitorina li ojiji iyẹ́-apa rẹ li emi o ma yọ̀.

8. Ọkàn mi ntọ̀ ọ lẹhin girigiri: ọwọ ọtún rẹ li o gbé mi ró.

9. Ṣugbọn awọn ti nwá ọkàn mi lati pa a run, nwọn o lọ si iha isalẹ-ilẹ.

10. Nwọn o ti ọwọ idà ṣubu: nwọn o si ṣe ijẹ fun kọ̀lọkọlọ.

O. Daf 63