6. Nigbati mo ba ranti rẹ lori ẹní mi, ti emi si nṣe aṣaro rẹ ni iṣọ oru.
7. Nitoripe iwọ li o ti nṣe iranlọwọ mi, nitorina li ojiji iyẹ́-apa rẹ li emi o ma yọ̀.
8. Ọkàn mi ntọ̀ ọ lẹhin girigiri: ọwọ ọtún rẹ li o gbé mi ró.
9. Ṣugbọn awọn ti nwá ọkàn mi lati pa a run, nwọn o lọ si iha isalẹ-ilẹ.
10. Nwọn o ti ọwọ idà ṣubu: nwọn o si ṣe ijẹ fun kọ̀lọkọlọ.
11. Ṣugbọn ọba yio ma yọ̀ ninu Ọlọrun; olukuluku ẹniti o nfi i bura ni yio ṣogo: ṣugbọn awọn ti nṣeke li a o pa li ẹnu mọ́.