O. Daf 61:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. GBỌ́ ẹkún mi, Ọlọrun; fiye si adura mi.

2. Lati opin aiye wá li emi o kigbe pè ọ, nigbati o rẹ̀ aiya mi, fà mi lọ si apata ti o ga jù mi lọ.

3. Nitori iwọ li o ti nṣe àbo fun mi, ati ile-iṣọ agbara lọwọ ọta nì.

4. Emi o joko ninu agọ rẹ lailai: jẹ ki emi ri àbo ni iyẹ-apa rẹ.

5. Nitoripe iwọ, Ọlọrun, li o ti gbọ́ ẹjẹ́ mi: iwọ ti fi ogún awọn ti o bẹ̀ru orukọ rẹ fun mi.

O. Daf 61