5. Nitoriti kò si iranti rẹ ninu okú: ninu isa okú tani yio dupẹ fun ọ?
6. Agara ikerora mi da mi: li oru gbogbo li emi nmu ẹní mi fó li oju omi; emi fi omije mi rin ibusùn mi.
7. Oju mi bajẹ tan nitori ibinujẹ; o di ogbó tan nitori gbogbo awọn ọta mi.
8. Ẹ lọ kuro lọdọ mi, gbogbo ẹnyin oniṣẹ ẹ̀ṣẹ; nitori ti Oluwa gbọ́ ohùn ẹkún mi.
9. Oluwa gbọ́ ẹ̀bẹ mi; Oluwa yio gbà adura mi.
10. Oju yio tì gbogbo awọn ọta mi, ara yio sì kan wọn gogo: nwọn o pada, oju yio tì wọn lojíji.