O. Daf 55:6-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Emi si wipe, A! iba ṣe pe emi ni iyẹ-apa bi àdaba! emi iba fò lọ, emi a si simi.

7. Kiyesi i, emi iba rìn lọ si ọ̀na jijin rére, emi a si ma gbe li aginju.

8. Emi iba yara sa asala mi kuro ninu ẹfufu lile ati iji na.

9. Oluwa, ṣe iparun, ki o si yà wọn li ahọn: nitori ti mo ri ìwa agbara ati ijà ni ilu na.

10. Ọsan ati oru ni nwọn fi nrìn odi rẹ̀ kiri: ìwa-ika pẹlu ati ikãnu mbẹ li arin rẹ̀.

11. Ìwa buburu mbẹ li arin rẹ̀: ẹ̀tan ati eke kò kuro ni igboro rẹ̀.

12. Nitoriti kì iṣe ọta li o gàn mi: njẹ emi iba pa a mọra: bẹ̃ni kì iṣe ẹniti o korira mi li o gbé ara rẹ̀ ga si mi; njẹ emi iba fi ara mi pamọ́ kuro lọdọ rẹ̀:

13. Ṣugbọn iwọ ni, ọkunrin ọ̀gba mi, amọ̀na mi, ati ojulumọ mi.

14. Awa jumọ gbimọ didùn, awa si kẹgbẹ rìn wọ̀ ile Ọlọrun lọ.

O. Daf 55