13. Ṣugbọn iwọ ni, ọkunrin ọ̀gba mi, amọ̀na mi, ati ojulumọ mi.
14. Awa jumọ gbimọ didùn, awa si kẹgbẹ rìn wọ̀ ile Ọlọrun lọ.
15. Ki ikú ki o dì wọn mu, ki nwọn ki o si lọ lãye si isa-okú: nitori ti ìwa buburu mbẹ ni ibujoko wọn, ati ninu wọn.
16. Bi o ṣe ti emi ni, emi o kepè Ọlọrun; Oluwa yio si gbà mi.
17. Li alẹ, li owurọ, ati li ọsan, li emi o ma gbadura, ti emi o si ma kigbe kikan: on o si gbohùn mi.
18. O ti gbà ọkàn mi silẹ li alafia lọwọ ogun ti o ti dó tì mi: nitoripe pẹlu ọ̀pọlọpọ enia ni nwọn dide si mi.
19. Ọlọrun yio gbọ́, yio si pọ́n wọn loju, ani ẹniti o ti joko lati igbani. Nitoriti nwọn kò ni ayipada, nwọn kò si bẹ̀ru Ọlọrun.