1. ỌLỌRUN gbà mi nipa orukọ rẹ, si ṣe idajọ mi nipa agbara rẹ.
2. Gbọ́ adura mi, Ọlọrun; fi eti si ọ̀rọ ẹnu mi.
3. Nitoriti awọn alejò dide si mi, awọn aninilara si nwá ọkàn mi: nwọn kò kà Ọlọrun si li oju wọn.
4. Kiyesi i, Ọlọrun li oluranlọwọ mi: Oluwa wà pẹlu awọn ti o gbé ọkàn mi duro.