1. AṢIWERE wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọlọrun kò si. Nwọn bajẹ nwọn si nṣe irira ẹ̀ṣẹ: kò si ẹniti o nṣe rere.
2. Ọlọrun bojuwo ilẹ lati ọrun wá sara awọn ọmọ enia, lati wò bi ẹnikan wà ti oye ye, ti o si nwá Ọlọrun.
3. Gbogbo wọn li o si pada sẹhin, nwọn si di elẽri patapata: kò si ẹniti nṣe rere, kò si ẹnikan.