17. Wò o, iwọ sa korira ẹkọ́, iwọ si ti ṣá ọ̀rọ mi tì lẹhin rẹ.
18. Nigbati iwọ ri olè, nigbana ni iwọ ba a mọ̀ ọ pọ̀, iwọ si ba awọn àgbere ṣe ajọpin.
19. Iwọ fi ẹnu rẹ fun buburu, ati ahọn rẹ npete ẹ̀tan.
20. Iwọ joko, iwọ si sọ̀rọ si arakunrin rẹ: iwọ mba orukọ ọmọ iya rẹ jẹ.
21. Nkan wọnyi ni iwọ ṣe emi si dakẹ; iwọ ṣebi emi tilẹ dabi iru iwọ tikararẹ; emi o ba ọ wi, emi o si kà wọn li ẹsẹ-ẹsẹ ni oju rẹ.
22. Njẹ rò eyi, ẹnyin ti o gbagbe Ọlọrun, ki emi ki o má ba fà nyin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ti kò si olugbala.
23. Ẹnikẹni ti o ba ru ẹbọ iyìn, o yìn mi logo: ati ẹniti o ba mu ọ̀na ọ̀rọ rẹ̀ tọ́ li emi o fi igbala Ọlọrun hàn fun.