O. Daf 50:10-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Nitori gbogbo ẹran igbo ni ti emi, ati ẹrankẹran lori ẹgbẹrun òke.

11. Emi mọ̀ gbogbo ẹiyẹ awọn oke nla: ati ẹranko igbẹ ni ti emi.

12. Bi ebi npa mi, emi kì yio sọ fun ọ: nitori pe aiye ni ti emi, ati ẹkún inu rẹ̀.

13. Emi o ha jẹ ẹran malu, tabi emi a ma mu ẹ̀jẹ ewurẹ bi?

14. Ru ẹbọ-ọpẹ si Ọlọrun, ki o si san ẹjẹ́ rẹ fun Ọga-ogo.

15. Ki o si kepè mi ni ọjọ ipọnju: emi o gbà ọ, iwọ o si ma yìn mi logo.

16. Ṣugbọn Ọlọrun wi fun enia buburu pe, Kini iwọ ni ifi ṣe lati ma sọ̀rọ ilana mi, tabi ti iwọ fi nmu majẹmu mi li ẹnu rẹ?

17. Wò o, iwọ sa korira ẹkọ́, iwọ si ti ṣá ọ̀rọ mi tì lẹhin rẹ.

18. Nigbati iwọ ri olè, nigbana ni iwọ ba a mọ̀ ọ pọ̀, iwọ si ba awọn àgbere ṣe ajọpin.

19. Iwọ fi ẹnu rẹ fun buburu, ati ahọn rẹ npete ẹ̀tan.

20. Iwọ joko, iwọ si sọ̀rọ si arakunrin rẹ: iwọ mba orukọ ọmọ iya rẹ jẹ.

21. Nkan wọnyi ni iwọ ṣe emi si dakẹ; iwọ ṣebi emi tilẹ dabi iru iwọ tikararẹ; emi o ba ọ wi, emi o si kà wọn li ẹsẹ-ẹsẹ ni oju rẹ.

O. Daf 50