O. Daf 42:9-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Emi o wi fun Ọlọrun, apata mi pe, Ẽṣe ti iwọ fi gbagbe mi? ẽṣe ti emi fi nrìn ni ìgbawẹ nitori inilara ọta nì.

10. Bi ẹnipe idà ninu egungun mi li ẹ̀gan ti awọn ọta mi ngàn mi; nigbati nwọn nwi fun mi lojojumọ pe, Ọlọrun rẹ dà?

11. Ẽṣe ti ori rẹ fi tẹ̀ba, iwọ ọkàn mi? ẽṣe ti ara rẹ kò fi lelẹ ninu mi? iwọ ṣe ireti niti Ọlọrun; nitori emi o sa ma yìn i sibẹ, ẹniti iṣe iranlọwọ oju mi ati Ọlọrun mi.

O. Daf 42