O. Daf 40:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NI diduro emi duro de Oluwa; o si dẹti si mi, o si gbohun ẹkún mi.

2. O si mu mi gòke pẹlu lati inu iho iparun jade wá, lati inu erupẹ ẹrẹ̀, o si fi ẹsẹ mi ka ori apata, o si fi iṣisẹ mi lelẹ.

3. O si fi orin titun si mi li ẹnu, ani orin iyìn si Ọlọrun wa: ọ̀pọ enia ni yio ri i, ti yio si bẹ̀ru, ti yio si gbẹkẹle Oluwa.

4. Ibukún ni fun ọkunrin na ti o fi Oluwa ṣe igbẹkẹle rẹ̀, ti kò si ka onirera si, tabi iru awọn ti nyà si iha eke.

5. Oluwa Ọlọrun mi ọ̀pọlọpọ ni iṣẹ iyanu ti iwọ ti nṣe, ati ìro inu rẹ sipa ti wa: a kò le kà wọn fun ọ li ẹsẹ-ẹsẹ: bi emi o wi ti emi o sọ̀rọ wọn, nwọn jù ohun kikà lọ.

6. Ẹbọ ati ọrẹ iwọ kò fẹ: eti mi ni iwọ ti ṣi: ọrẹ-ẹbọ sisun, ati ọrẹ-ẹbọ ẹ̀ṣẹ on ni iwọ kò bère.

O. Daf 40