5. Ọgbẹ mi nrùn, o si dibajẹ nitori were mi.
6. Emi njowere; ori mi tẹ̀ ba gidigidi; emi nṣọ̀fọ kiri li gbogbo ọjọ.
7. Nitoriti iha mi kún fun àrun ẹgbin; kò si si ibi yiyè li ara mi.
8. Ara mi hù, o si kan bajẹ; emi ti nkerora nitori aisimi aiya mi.
9. Oluwa, gbogbo ifẹ mi mbẹ niwaju rẹ; ikerora mi kò si pamọ́ kuro lọdọ rẹ.
10. Aiya mi nmi-hẹlẹ, agbara mi yẹ̀ mi silẹ: bi o ṣe ti imọlẹ oju mi ni, kò si lara mi.