O. Daf 34:2-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ọkàn mi yio ma ṣogo rẹ̀ niti Oluwa: awọn onirẹlẹ yio gbọ́, inu wọn yio si ma dùn.

3. Gbé Oluwa ga pẹlu mi, ki a si jumọ gbé orukọ rẹ̀ leke.

4. Emi ṣe afẹri Oluwa, o si gbohùn mi; o si gbà mi kuro ninu gbogbo ìbẹru mi.

5. Nwọn wò o, imọlẹ si mọ́ wọn: oju kò si tì wọn.

6. Ọkunrin olupọnju yi kigbe pè, Oluwa si gbohùn rẹ̀, o si gbà a ninu gbogbo ipọnju rẹ̀:

7. Angeli Oluwa yi awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀ ká, o si gbà wọn.

8. Tọ́ ọ wò, ki o si ri pe, rere ni Oluwa: alabukún fun li ọkunrin na ti o gbẹkẹle e.

O. Daf 34