O. Daf 30:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EMI o kokiki rẹ, Oluwa; nitori iwọ li o gbé mi leke, ti iwọ kò si jẹ ki awọn ọta mi ki ó yọ̀ mi.

2. Oluwa Ọlọrun mi, emi kigbe pè ọ, iwọ si ti mu mi lara da.

3. Oluwa, iwọ ti yọ ọkàn mi jade kuro ninu isa-okú: iwọ o si pa mi mọ́ lãye, ki emi ki o má ba lọ sinu iho.

O. Daf 30