O. Daf 24:7-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ẹ gbé ori nyin soke, ẹnyin ẹnu-ọ̀na; ki a si gbé nyin soke, ẹnyin ilẹkun aiyeraiye: ki Ọba ogo ki o wọ̀ inu ile wa.

8. Tali Ọba ogo yi? Oluwa ti o le, ti o si lagbara, Oluwa ti o lagbara li ogun.

9. Ẹ gbé ori nyin soke, ẹnyin ẹnu-ọ̀na; ani ki ẹ gbé wọn soke, ẹnyin ilẹkun aiyeraiye: ki Ọba ogo ki o wọ̀ inu ile wa.

10. Tali Ọba ogo yi? Oluwa awọn ọmọ-ogun; on na li Ọba ogo.

O. Daf 24