O. Daf 22:3-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Ṣugbọn mimọ́ ni Iwọ, ẹniti o tẹ̀ iyìn Israeli do.

4. Awọn baba wa gbẹkẹle ọ: nwọn gbẹkẹle, iwọ si gbà wọn.

5. Nwọn kigbe pè ọ, a si gbà wọn: nwọn gbẹkẹle ọ, nwọn kò si dãmu.

6. Ṣugbọn kòkoro li emi, kì isi iṣe enia; ẹ̀gan awọn enia, ati ẹlẹya awọn enia.

7. Gbogbo awọn ti o ri mi nfi mi rẹrin ẹlẹya: nwọn nyọ ṣuti ète wọn, nwọn nmì ori pe,

8. Jẹ́ ki o gbẹkẹle Oluwa, on o gbà a là; jẹ ki o gbà a là nitori inu rẹ̀ dùn si i.

9. Ṣugbọn iwọ li ẹniti o mu mi jade lati inu wá: iwọ li o mu mi wà li ailewu, nigbati mo rọ̀ mọ́ ọmu iya mi.

10. Iwọ li a ti fi mi le lọwọ lati inu iya mi wá: iwọ li Ọlọrun mi lati inu iya mi wá.

11. Máṣe jina si mi; nitori ti iyọnu sunmọ etile; nitoriti kò si oluranlọwọ.

O. Daf 22