O. Daf 22:13-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Nwọn yà ẹnu wọn si mi, bi kiniun ti ndọdẹ kiri, ti nké ramuramu.

14. A tú mi danu bi omi, gbogbo egungun mi si yẹ̀ lori ike: ọkàn mi dabi ida; o yọ́ larin inu mi.

15. Agbara mi di gbigbẹ bi apãdi: ahọn mi si lẹ̀ mọ́ mi li ẹrẹkẹ; iwọ o mu mi dubulẹ ninu erupẹ ikú.

16. Nitoriti awọn aja yi mi ka: ijọ awọn enia buburu ti ká mi mọ́: nwọn lu mi li ọwọ, nwọn si lu mi li ẹsẹ.

17. Mo le kaye gbogbo egungun mi: nwọn tẹjumọ mi; nwọn nwò mi sùn.

18. Nwọn pín aṣọ mi fun ara wọn, nwọn si ṣẹ́ keké le aṣọ-ileke mi.

19. Ṣugbọn iwọ máṣe jina si mi, Oluwa: agbara mi, yara lati ràn mi lọwọ.

20. Gbà ọkàn mi lọwọ idà; ẹni mi kanna lọwọ agbara aja nì.

21. Gbà mi kuro li ẹnu kiniun nì; ki iwọ ki o si gbohùn mi lati ibi iwo awọn agbanrere.

22. Emi o sọ̀rọ orukọ rẹ fun awọn arakunrin mi: li awujọ ijọ li emi o ma yìn ọ,

23. Ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ẹ yìn i; gbogbo ẹnyin iru-ọmọ Jakobu, ẹ yìn i logo: ki ẹ si ma bẹ̀ru rẹ̀ gidigidi, gbogbo ẹnyin irú-ọmọ Israeli.

O. Daf 22