O. Daf 18:3-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Emi o kepè Oluwa, ti o yẹ lati ma yìn; bẹ̃li a o si gbà mi lọwọ awọn ọta mi.

4. Irora ikú yi mi ka, ati iṣàn-omi awọn enia buburu dẹ̀ruba mi.

5. Irora ipò okú yi mi kakiri: ikẹkun ikú dì mi mu.

6. Ninu ìṣẹ́ mi emi kepè Oluwa, emi si sọkun pe Ọlọrun mi: o gbohùn mi lati inu tempili rẹ̀ wá, ẹkún mi si wá si iwaju rẹ̀, ani si eti rẹ̀.

7. Nigbana ni ilẹ mì, o si wariri: ipilẹ òke pẹlu ṣidi, o si mì, nitoriti o binu.

8. Ẹ̃fin ti iho imu rẹ̀ jade, ati iná lati ẹnu rẹ̀ wá njonirun: ẹyín gbiná nipasẹ rẹ̀.

O. Daf 18