O. Daf 144:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUBUKÚN li oluwa apata mi, ẹniti o kọ́ ọwọ mi li ogun, ati ika mi ni ìja:

2. Õre mi, ati odi-agbara mi; ile-iṣọ giga, ati olugbala mi; asà mi, ati ẹniti mo gbẹkẹle; eniti o tẹri awọn enia mi ba labẹ mi.

3. Oluwa, kili enia, ti iwọ fi nkiye si i! tabi ọmọ enia, ti iwọ fi nronú rẹ̀!

O. Daf 144