O. Daf 140:7-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ọlọrun Oluwa, agbara igbala mi, iwọ li o bò ori mi mọlẹ li ọjọ ìja.

8. Oluwa, máṣe fi ifẹ enia buburu fun u: máṣe kún ọgbọ́n buburu rẹ̀ lọwọ: ki nwọn ki o má ba gbé ara wọn ga.

9. Bi o ṣe ti ori awọn ti o yi mi ká kiri ni, jẹ ki ìka ète ara wọn ki o bò wọn mọlẹ.

10. A o da ẹyin iná si wọn lara: on o wọ́ wọn lọ sinu iná, sinu ọgbun omi jijin, ki nwọn ki o má le dide mọ́.

11. Máṣe jẹ ki alahọn buburu ki o fi ẹsẹ mulẹ li aiye: ibi ni yio ma dọdẹ ọkunrin ìka nì lati bì i ṣubu.

O. Daf 140