O. Daf 140:11-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Máṣe jẹ ki alahọn buburu ki o fi ẹsẹ mulẹ li aiye: ibi ni yio ma dọdẹ ọkunrin ìka nì lati bì i ṣubu.

12. Emi mọ̀ pe, Oluwa yio mu ọ̀ran olupọnju duro, ati are awọn talaka.

13. Nitõtọ awọn olododo yio ma fi ọpẹ fun orukọ rẹ: awọn ẹni diduro-ṣinṣin yio ma gbe iwaju rẹ.

O. Daf 140