10. A o da ẹyin iná si wọn lara: on o wọ́ wọn lọ sinu iná, sinu ọgbun omi jijin, ki nwọn ki o má le dide mọ́.
11. Máṣe jẹ ki alahọn buburu ki o fi ẹsẹ mulẹ li aiye: ibi ni yio ma dọdẹ ọkunrin ìka nì lati bì i ṣubu.
12. Emi mọ̀ pe, Oluwa yio mu ọ̀ran olupọnju duro, ati are awọn talaka.
13. Nitõtọ awọn olododo yio ma fi ọpẹ fun orukọ rẹ: awọn ẹni diduro-ṣinṣin yio ma gbe iwaju rẹ.